2 Corinthians 5:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò tún nílò pé kí á máa pọ́n ara wa fun yín mọ́. Ṣugbọn èyí yóo jẹ́ anfaani fun yín láti máa fi wá ṣògo, kí ẹ lè máa rí ohun wí fún àwọn tí wọn ń ṣògo nípa nǹkan ti òde ara, tí kì í ṣe nípa nǹkan ti inú ọkàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lodé ara kì í ṣe ní ọkàn.