2 Corinthians 5:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, a jẹ́ aṣojú fún Kristi. Ó dàbí ẹni pé àwa ni Ọlọrun ń lò láti fi bẹ̀ yín. A fi orúkọ Kristi bẹ̀ yín, ẹ bá Ọlọrun rẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kírísítì, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín nípò Kírísítì, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,”