2 Corinthians 6:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Ọlọrun sọ pé, “Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé; mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.” Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Nitori o wipe, emi ti gbohùn rẹ li akokò itẹwọgbà, ati li ọjọ igbala ni mo si ti ràn ọ lọwọ: kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí o wí pé, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ, àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Èmi wí fún ọ, nísínsín yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísínsín yìí ní ni ọjọ́ ìgbàlà.