2 Corinthians 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí bí mo bá ti sọ ohunkohun nípa yín, tí mo sì ti fi ọwọ́ yín sọ̀yà, ẹ kò dójú tì mí. Ṣugbọn bí ó ti jẹ́ pé òtítọ́ ni gbogbo nǹkan tí a ti sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ náà ni ọwọ́ yín tí a fi sọ̀yà fún Titu jẹ́ òtítọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi mo tilẹ ti leri ohunkohun fun u nitori nyin, a kò dojuti mi; ṣugbọn gẹgẹ bi awa ti sọ ohun gbogbo fun nyin li otitọ, gẹgẹ bẹ̃li ori ti a lé niwaju Titu si jasi otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójú tì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Títù sì já sí òtítọ́.