2 Corinthians 7:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo ni igboiya nla lati ba nyin sọ̀rọ, iṣogo mi lori nyin pọ̀, mo kun fun itunu, mo si nyọ̀ rekọja ninu gbogbo ipọnju wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo ní ìgbóyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.