2 Corinthians 7:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí a dé Masedonia, ọkàn wa kò balẹ̀ rárá. Wahala ni lọ́tùn-ún lósì, ìjà lóde, ẹ̀rù ninu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ìja mbẹ lode, ẹ̀ru mbẹ ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedóníà, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú.