2 Corinthians 7:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ṣugbọn nisinsinyii mo láyọ̀. Kì í ṣe nítorí pé ó bà yín lọ́kàn jẹ́, ṣugbọn nítorí pé bíbà tí ó bà yín lọ́kàn jẹ́ ni ó jẹ́ kí ẹ ronupiwada. Nítorí ẹ farada ìbànújẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, kí ẹ má baà pàdánù nítorí ohun tí a ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi yọ̀ nisisiyi, kì iṣe nitoriti a mu inu nyin bajẹ, ṣugbọn nitoriti a mu inu nyin bajẹ si ironupiwada: nitoriti a mu inu nyin bajẹ bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, ki ẹnyin ki o maṣe tipasẹ wa pàdanù li ohunkohun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun.