2 Corinthians 8:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn ẹniti a ti yàn pẹlu lati ọdọ ijọ wá lati mã bá wa rìn kiri ninu ọran ore-ọfẹ yi, ti awa nṣe iranṣẹ rẹ̀ fun ogo Oluwa, ati imura-tẹlẹ wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀ràn oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra tẹ́lẹ̀ wa.