2 Corinthians 8:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ti Titu, ẹlẹgbẹ́ mi ati alábàáṣiṣẹ́ mi ni ninu ohun tí ó kàn yín. Ní ti àwọn arakunrin wa, òjíṣẹ́ àwọn ìjọ ni wọ́n, Ògo Kristi sì ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnikẹni ba mbère ẹniti Titu iṣe, ẹlẹgbẹ ati olubaṣiṣẹ mi ni nitori nyin: tabi awọn arakunrin wa li ẹnikẹni mbère ni, iranṣẹ ijọ ni nwọn iṣe, ati ogo Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Títù jẹ́, ẹlẹ́gbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń bèèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kírísítì.