2 Corinthians 9:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí àwọn eniyan yóo fi máa yin Ọlọrun fún rírẹ̀ tí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ igbagbọ yín ninu ìyìn rere ti Kristi, ati nítorí ìlawọ́ yín ninu iṣẹ́ yìí fún wọn ati fún gbogbo onigbagbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin ti nwọn fi iṣẹ-isin yi dan nyin wo, nwọn yin Ọlọrun li ogo fun itẹriba ijẹwọ́ nyin si ihinrere Kristi, ati fun ilàwọ ìdawó nyin fun wọn ati fun gbogbo enia;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́-ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìyìn rere Kírísítì àti nípa ìlawọ́ ìdánwò yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn.