2 Corinthians 9:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí mo mọ àníyàn yín, mo sì ti ń fi ọwọ́ sọ̀yà nípa yín fún àwọn ará Masedonia, pé Akaya ti parí ètò tiwọn láti ọdún tí ó kọjá. Ìtara yín sì ti mú kí ọpọlọpọ túbọ̀ múra sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori mo mọ̀ imura-tẹlẹ nyin, eyiti mo fi yangàn fun awọn ara Makedonia nitori nyin, pe, Akaia ti mura tan niwọn ọdún kan ti o kọja; itara nyin si ti rú ọ̀pọlọpọ soke.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí mo mọ ìmúra tẹ́lẹ̀ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedóníà nítorí yín, pé, Ákáyà ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.