2 Corinthians 9:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, mo rí i pé ó di dandan pé kí n bẹ àwọn arakunrin láti ṣiwaju mi wá sọ́dọ̀ yín, kí wọ́n ṣe ètò sílẹ̀ nípa ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí, kí ó jẹ́ pé yóo ti wà nílẹ̀ kí n tó dé. Èyí yóo mú kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, kò ní jẹ́ ti ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni mo ṣe rò pe o yẹ lati gbà awọn arakunrin niyanju, ki nwọn ki o ṣaju tọ̀ nyin wá, ki nwọn ki o si mura ẹ̀bun nyin silẹ, ti ẹ ti ṣe ileri tẹlẹ ki a le ṣe eyi na silẹ, ki o le jasi bi ohun ẹ̀bun, ki o má si ṣe dabi ti ojukòkoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ̀ bí ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti ìfipágbà.