2 John 1:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo ti lẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alabapin pẹ̀lú yín, síbẹ̀èmi kò fẹ́ lo ìwé-ìkọ́wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.