2 Kings 1:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíjà sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.