2 Kings 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si tun rán olori-ogun ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, Bayi li ọba wi, yara sọ̀kalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Èlíjà. Balógun náà sì wí fún un pé, “Èniyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba ṣọ, ‘Ṣọ̀kalẹ̀ kánkán!’ ”