2 Kings 1:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Elija sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, “Nítorí pé o rán oníṣẹ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bí ẹni pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, kíkú ni o óo kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ ran onṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli lati bère ọ̀rọ rẹ̀? nitorina iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì láti lọ ṣe ìwádìí? Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò níi dìde lórí ibùsùn tí o dúbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!”