2 Kings 1:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahasaya sì kú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA tí Elija sọ. Ṣugbọn nítorí pé kò ní ọmọkunrin kankan Joramu, arakunrin rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀, ní ọdún keji tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni o kú gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti Elijah ti sọ. Jehoramu si jọba ni ipò rẹ̀, li ọdun keji Jehoramu ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda, nitoriti kò ni ọmọkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí Èlíjà ti sọ. Nítorí Áhásáyà kò ní ọmọ, Jéhórámù jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jéhórámù ọmọ Jèhósáfátì ọba Júdà.