2 Kings 1:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahasaya ọba ṣubú láti orí òkè ilé rẹ̀ ní Samaria, ó sì farapa pupọ. Nítorí náà ni ó ṣe rán oníṣẹ́ lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bóyá òun yóo sàn ninu àìsàn náà tabi òun kò ní sàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahasiah si ṣubu lãrin fèrese ọlọnà kan ni iyara òke rẹ̀ ti o wà ni Samaria, o si ṣàisan: o si rán awọn onṣẹ o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, bi emi o là ninu aisan yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí Áhásáyà ti ṣubú láàrin fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Ṣamáríà, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù, òrìṣà Ékírónì, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”