2 Kings 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn angẹli OLUWA kan pàṣẹ fún wolii Elija, ará Tiṣibe pé, “Lọ pàdé àwọn oníṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi ń lọ wádìí nǹkan lọ́dọ̀ Baalisebubu, oriṣa Ekironi?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn angeli Oluwa wi fun Elijah, ara Tiṣbi pe, Dide, gòke lọ ipade awọn onṣẹ ọba Samaria, ki o si wi fun wọn pe, Kò ṣe pe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni ẹnyin fi nlọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì OLÚWA wí fún Èlíjà ará Tíṣíbì pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Ṣámáríà kí o sì bèèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Bálísébúbù òrìṣà Ékírónì?’