2 Kings 1:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba bá rán ọ̀gágun kan ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n lọ mú Elija. Ọ̀gágun náà rí Elija níbi tí ó jókòó sí ní téńté òkè, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀. Balógun náà sì gòkè tọ Èlíjà lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, ‘Sọ̀kalẹ̀ wá!’ ”