2 Kings 10:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehu pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú wọn láàyè. Wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ibi kòtò tí ó wà ní Bẹtekedi. Gbogbo wọn jẹ́ mejilelogoji, kò sì dá ọ̀kankan ninu wọn sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Ẹ mu wọn lãyè, nwọn si mu wọn lãyè, nwọn si pa wọn nibi iho ile irẹ́run agùtan, ani ọkunrin mejilelogoji, bẹ̃ni kò si kù ẹnikan wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Mú wọn láàyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.