2 Kings 10:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehu tún ń lọ, ó pàdé Jehonadabu, ọmọ Rekabu, tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehu kí i tán, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ọkàn rẹ mọ́ sí mi bí ọkàn mi ti mọ́ sí ọ?” Jehonadabu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Jehu dáhùn, ó ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.” Ó bá na ọwọ́ sí Jehu, Jehu sì fà á sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si jade nibẹ, o ri Jehonadabu ọmọ Rekabu mbọ̀wá ipade rẹ̀; o si sure fun u, o si wi fun u pe, Ọkàn rẹ ha ṣe dede bi ọkàn mi ti ri si ọkàn rẹ? Jehonadabu si dahùn wipe, Bẹ̃ni. Bi bẹ̃ni, njẹ fun mi li ọwọ rẹ. O si fun u li ọwọ rẹ̀; on si fà a sọdọ rẹ̀ sinu kẹkẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò níbẹ̀, ó wá sórí Jéhónádábù ọmọ Rékábù tí ó wà ní ọ̀nà rẹ̀ láti lọ bá a. Jéhù kí i, ó sì wí pé, “Ṣé ìwọ wà ní ìbárẹ́ pẹ̀lú mi, bí èmi ti wa pẹ̀lú ù rẹ?” “Èmi wà,” Jéhónádábù dáhùn. “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀,” Jéhù wí, “fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jéhù sì ràn án ọ́ lọ́wọ́ sókè sí inú kẹ̀kẹ́.