2 Kings 10:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé Samaria, Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu, kò sì fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Elija.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de Samaria, o pa gbogbo awọn ti o kù fun Ahabu ni Samaria, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ fun Elijah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jéhù wá sí Ṣamáríà, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Áhábù; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí a sọ sí Èlíjà.