2 Kings 10:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wolii Baali ati àwọn tí ń bọ ọ́ ati àwọn alufaa rẹ̀ wá fún mi. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe aláìwá nítorí mo fẹ́ ṣe ìrúbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá, pípa ni a óo pa á.” Ṣugbọn Jehu ń ṣe èyí láti rí ààyè pa gbogbo àwọn olùsìn Baali run ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì jọ, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀. Rí i wí pé, kò sí nǹkankan tí ó ń sọnù nítorí ẹ̀mi yóò rú ẹbọ ńlá fún Báálì. Ẹnìkíní tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láàyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jéhù fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Báálì run.