2 Kings 10:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ó rán ọ̀rọ̀ káàkiri Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Báálì sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkángun èkíní títí dé èkejì.