2 Kings 10:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn èyí, Jehu ati Jehonadabu lọ sinu ilé ìsìn náà, ó ní, “Ẹ rí i dájú pé àwọn olùsìn Baali nìkan ni wọ́n wà níhìn-ín, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń sin OLUWA níbí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Jéhù àti Jéhónádábù ọmọ Rékábù lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì. Jéhù sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Báálì pé, “Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Báálì.”