2 Kings 10:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òun pẹlu Jehonadabu bá wọlé láti rú ẹbọ sísun sí Baali. Ṣugbọn Jehu ti fi ọgọrin ọkunrin yí ilé ìsìn náà po, ó sì ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọ́n wá jọ́sìn níbẹ̀. Ó ní ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí ẹnìkan lọ, pípa ni a óo pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ọrẹ sísun. Nísinsìn yìí Jéhù ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sá lọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí ì rẹ.”