2 Kings 10:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Jehu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó dára lójú mi, o ti ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe sí ilé Ahabu, tí o ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn mi, àwọn ọmọ rẹ, títí dé ìran kẹrin, yóo máa jọba ní Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fún Jéhù pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Áhábù gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”