2 Kings 10:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Jehu kò kíyèsára kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Òfin OLUWA Ọlọrun Israẹli; ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu tí ó mú kí Israẹli hù ni ó tẹ̀lé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣíbẹ̀ Jéhù kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù èyí tí ó ṣokùnfà Ísírẹ́lì láti dá.