2 Kings 10:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni olùpínfúnni a fún, olórí ìlú ńlá, àwọn àgbààgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jéhù: “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; Ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù.”