2 Kings 11:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà ni ó mú Joaṣi, ọmọ ọba jáde síta, ó fi adé ọba dé e lórí, ó sì fún un ní ìwé òfin. Lẹ́yìn náà ni ó da òróró sí i lórí láti fi jọba. Àwọn eniyan pàtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe pé, “Kabiyesi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóíádà mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”