2 Kings 11:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó wo ọ̀kánkán, ó wò, ó rí ọba náà tí ó dúró ní ẹ̀bá òpó, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣà, ó sì rí i tí àwọn olórí ogun ati àwọn afunfèrè yí i ká, tí àwọn eniyan sì ń fi ayọ̀ pariwo, tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Atalaya fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn ìjòyè àti àwọn afọ̀npè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀ wọ́n sì ń fọ̀npè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataláyà fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”