2 Kings 11:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehoiada kò fẹ́ kí wọ́n pa Atalaya ninu ilé OLUWA, nítorí náà ó pàṣẹ fún àwọn olórí ogun, ó ní, “Ẹ mú un jáde, kí ó wà ní ààrin yín bí ẹ ti ń mú un lọ; ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbà á là, pípa ni kí ẹ pa á.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóíádà àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrin àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.”