2 Kings 11:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òun ati àwọn olórí ogun ati àwọn tí wọ́n ń ṣọ́ ọba ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin sin ọba láti ilé OLUWA lọ sí ààfin. Ọba gba ẹnu ọ̀nà àwọn olùṣọ́ wọlé, ó sì jókòó lórí ìtẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, ati awọn ẹ̀ṣọ, ati gbogbo enia ilẹ na; nwọn si mu ọba sọ̀kalẹ lati ile Oluwa wá, nwọn si gbà oju ẹnu-ọ̀na ẹ̀ṣọ wọ̀ ile ọba. O si joko lori ìtẹ awọn ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọọrún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú àyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba.