2 Kings 11:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ní ọdún keje, Jehoiada ranṣẹ pe àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ọba wá sí ilé OLUWA pẹlu àwọn olórí ogun tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Ó bá wọn dá majẹmu, ó sì mú kí wọ́n búra láti fọwọsowọpọ pẹlu òun ninu ohun tí ó fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ó fi ọmọ Ahasaya ọba hàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun keje Jehoiada si ranṣẹ o si mu awọn olori lori ọ̀rọrún, pẹlu awọn balogun, ati awọn olùṣọ, o si mu wọn wá si ọdọ rẹ̀ sinu ile Oluwa, o si ba wọn da majẹmu, o si mu wọn bura ni ile Oluwa, o si fi ọmọ ọba hàn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kéje, Jéhóíádà ránṣẹ́ sí àwọn olóórí ní ọrọrún àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.