2 Kings 11:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn yóo dáàbò bo ọba pẹlu idà ní ọwọ́ wọn, wọn yóo sì máa bá a lọ sí ibikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si pa agbo yi ọba ka, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹniti o ba si wọ̀ arin ẹgbẹ́ ogun na, ki a pa a: ki ẹnyin ki o si wà pẹlu ọba bi o ti njade lọ, ati bi o ti mbọ̀wá ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbúdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”