2 Kings 11:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn olórí ogun náà gbọ́ àṣẹ tí Jehoiada, alufaa, pa fún wọn, wọ́n sì kó àwọn ọmọ ogun wọn, tí wọ́n ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ati àwọn tí wọn yóo wọ iṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olórí àwọn ọrọọrún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jéhóíádà àlùfáà ti paà láṣẹ́. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jéhóíádà àlùfáà.