2 Kings 12:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí owó bá pọ̀ ninu àpótí náà, akọ̀wé ọba ati olórí Alufaa yóo ka owó náà, wọn yóo sì dì í sinu àpò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati nwọn ri pe, owo pupọ̀ mbẹ ninu apoti na, ni akọwe ọba, ati olori alufa gòke wá, nwọn si dì i sinu apò, nwọn si kà iye owo ti a ri ninu ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.