2 Kings 12:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí wọ́n bá wọn owó náà, wọn yóo gbé àpò owó náà fún àwọn tí wọn ń ṣe àkóso ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo san owó fún àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati àwọn tí wọn ń kọ́lé;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi owo na ti a kà le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, awọn ti o nṣe abojuto ile Oluwa: nwọn si ná a fun awọn gbẹnagbẹna, ati awọn akọle, ti nṣiṣẹ ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA; Àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.