2 Kings 12:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò lò lára owó náà láti fi ra agbada fadaka, abọ́, fèrè, tabi àwọn ohun èlò wúrà tabi ti fadaka sí ilé OLUWA,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ninu owo ti a mu wá sinu ile Oluwa, a kò fi ṣe ọpọ́n fadakà, alumagàji fitila, awokoto, ipè ohun èlo wura tabi ohun elò fadakà kan fun ile Oluwa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, àlùmágàjí fìtílà, àwokòtò, ipè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.