2 Kings 12:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn wọn kò da owó ìtanràn ati owó ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ mọ́ owó fún àtúnṣe ilé OLUWA, nítorí pé àwọn alufaa ni wọ́n ni owó ìtanràn ati ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Owo ẹbọ irekọja ati owo ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni a kò mu wá sinu ile Oluwa: ti awọn alufa ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA: ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.