2 Kings 12:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joaṣi, ọba Juda, kó gbogbo àwọn ẹ̀bùn mímọ́ tí Jehoṣafati ati Jehoramu ati Ahasaya, àwọn baba ńlá rẹ̀ tí wọ́n ti jọba ṣáájú rẹ̀ yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati èyí tí òun pàápàá ti yà sọ́tọ̀ ati gbogbo wúrà tí ó wà ninu àwọn ilé ìṣúra ilé OLUWA ati èyí tí ó wà ní ààfin, ó fi wọ́n ranṣẹ sí Hasaeli, ọba Siria. Hasaeli bá kó ogun rẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoaṣi ọba Juda si mu gbogbo ohun èlo mimọ́ ti Jehoṣafati, ati Jehoramu, ati Ahasiah awọn baba rẹ̀, awọn ọba Juda ti yà si mimọ́, ati ohun mimọ́ tirẹ̀, ati gbogbo wura ti a ri nibi iṣura ile Oluwa, ati ni ile ọba, o si rán a si Hasaeli ọba Siria: on si lọ kuro ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jóásì ọba Júdà mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀—Jéhósáfátì, Jéhórámù àti Áhásáyà, àwọn ọba Júdà, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkálára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA àti níti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hásáélì; ọba Ṣíríà, tí ó sì fa padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù.