2 Kings 12:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Josakari, ọmọ Ṣimeati ati Jehosabadi, ọmọ Ṣomeri, àwọn olórí ogun, ni wọ́n pa á. Wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Amasaya ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Josakari ọmọ Simeati ati Jehosabadi ọmọ Ṣomeri, awọn iranṣẹ rẹ̀ pa a, o si kú; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn oníṣẹ́ tí ó pa á jẹ́ Jósábádì ọmọ Ṣíméátì àti Jéhósábádì ọmọ Ṣómérì. Ó kú, wọ́n sì sin-ín pẹ̀lú baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dáfídì. Ámásáyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.