2 Kings 12:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joaṣi pàṣẹ fún àwọn alufaa pé kí wọ́n máa kó àwọn owó ohun mímọ́ tí wọ́n mú wá sí ilé OLUWA pamọ́: ati gbogbo owó tí àwọn eniyan san fún ẹbọ ìgbà gbogbo ati èyí tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoaṣi si wi fun awọn alufa pe, Gbogbo owo ti a yà si mimọ́ ti a si mu wá sinu ile Oluwa, ani olukuluku owo ti o kọja, ati owo idiyele olukuluku, ati gbogbo owo ti o ti inu ọkàn olukuluku wá lati mu wá sinu ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóásì sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a múwá sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.