2 Kings 12:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Alufaa kọ̀ọ̀kan ni yóo máa tọ́jú owó tí wọ́n bá mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, yóo sì lo owó náà láti máa tún ilé OLUWA ṣe bí ó ti fẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún túntún ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA ṣe.”