2 Kings 12:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ó pe Jehoiada ati àwọn alufaa yòókù, ó bèèrè pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi tún ilé OLUWA ṣe? Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ gbọdọ̀ máa kó owó tí ẹ bá gbà sílẹ̀ fún àtúnṣe ilé OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ọba Jóásì pe Jéhóíádà àlùfáà àti àwọn àlùfáà yóòkù, ó sì bi wọ́n, pé “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin kò fi tún ìbàjẹ́ tí a ṣe sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA ṣe? Ẹ má ṣe gba owó mọ́ lọ́wọ́ àwọn afowópamọ́, ṣùgbọ́n ẹ gbé e kalẹ̀ fún túntun ilé tí a kọ́ fún OLÚWA ṣe.”