2 Kings 12:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Jehoiada gbé àpótí kan, ó lu ihò sí orí rẹ̀, ó gbé e sí ẹ̀bá pẹpẹ ìrúbọ ní ọwọ́ ọ̀tún tí eniyan bá wọ ilé OLUWA. Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA a sì máa kó owó tí àwọn eniyan bá mú wá sinu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jehoiada alufa mu apoti kan, o si dá ideri rẹ̀ lu, o si fi i si ẹba pẹpẹ na, li apa ọtún bi ẹnikan ti nwọ̀ inu ile Oluwa lọ: awọn alufa ti o si ntọju iloro na fi gbogbo owo ti a mu wá inu ile Oluwa sinu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóíádà àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún OLÚWA. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún OLÚWA.