2 Kings 13:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Ṣi fèrese ilà õrùn. On si ṣi i. Nigbana ni Eliṣa wipe, Ta. On si ta. O si wipe, Ọfà igbala Oluwa, ati ọfà igbala lọwọ Siria: nitori iwọ o kọlù awọn ara Siria ni Afeki, titi iwọ o fi run wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣí fèrèsé apá ìlà oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣéé: “Ta á!” Èlíṣà wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun OLÚWA; ọfà ìṣẹ́gun lórí Ṣíríà!” Èlíṣà kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Ṣíríà run pátapáta ní Áfékì.”