2 Kings 13:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Enia Ọlọrun na si binu si i, o si wipe, Iwọ iba ta lẹrinmarun tabi mẹfa; nigbana ni iwọ iba kọlù Siria titi iwọ iba fi run u: ṣugbọn nisisiyi iwọ o kọlù Siria nigbà mẹta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹẹ̀marùn-ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹfà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Ṣíríà àti pa á run pátapáta ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.”