2 Kings 13:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀. Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eliṣa si kú, nwọn si sìn i. Ẹgbẹ́ awọn ara Moabu si gbé ogun wá ilẹ na li amọdun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èlíṣà kú a sì sin ín. Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún.